|
IWURE 1 |
PRAYER 1 (Opening) |
|
Olódùmarè àwa omo rę dé, |
Olodumare we, the
children, have come |
|
Adé láti wá gba ìre tiwa, |
We have come to get
our blessings for today |
|
Asìn ńbè ọ lórúkọ odù
mérìndínlógún |
We are begging you in
the name of all the 16 major odu |
|
Kí o
gbó ìre tòní yí |
That you should
listen to the prayer of the day |
|
Bí o
bá gbọ kí o múu şę, |
When you hear our
prayer, please grant our request |
|
Kí o máa
śọ Baba wa |
Protect our Fathers |
|
Kí o
máa śọ Ìyá wa |
Protect our Mothers |
|
Kí o máa śọ Aya/Ọkọ wa |
Protect our
Wives/Husbands |
|
Kí o
máa śọ Ọmọ wa, |
Protect our Children |
|
Kí o máa śọ Alábàá gbélé
àti òré wa |
Protect our Neighbors
and Friends |
|
Títí tófi mó ibi tí aní
ẹni dé |
And extend your
protection to all our well-wishers |
|
Pàápàá àti àwọn mòlébí
wa |
Most especially our
relatives |
|
Afi ọlójó òní bè ó |
We beg you in the
name of the Orisha that rules today |
|
Kí o
fi yè dénú |
For you to be mindful
of what we are doing |
|
Kí o
fi yè dékùn |
For you to be mindful
of all our proceedings |
|
Kí o
fi yè dé gbogbo ara |
For you to be mindful
of all our generalities |
|
Bàbá awa Ọmọ rẹ là ń pè
ó |
Father, we the
children are calling upon you |
|
Èlà ìború Èlà bòyè Èlà
boşíşe |
Èlà ìború Èlà bòyè
Èlà boşíşe |
|
ORIN 1 |
SONG 1 (Repeat
of Opening) |
|
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi oò |
Acceptance of ÒRÌŞÀ
blessings from my voice |
|
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi |
Acceptance of ÒRÌŞÀ
blessings from my mouth, |
|
Gbogbo ìre tí mo bá mòmò
wí òò |
All my positive
affirmation and prayers |
|
Ni IRÚNMỌLÈ o gbàà |
Will be accepted by
the IRÚNMỌLÈ |
|
Yío gbàá òò |
Absolutely accepted |
|
. Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi |
Acceptance of ÒRÌŞÀ
blessings from my mouth, |
|
IWURE 2 |
PRAYER 2
(Closing) |
|
OLÓDÙMARÈ Oba Àjíkí |
Olodumare the King of
The Begining |
|
ÒDÙMÀRÈ Ọba Àjígè |
Odumare, the King of
Adulation |
|
Ògègé Ọba tó gbé ilé Ayé
dúró |
The axis of
equilibrium on which the world pivots |
|
Ògbàgbà ńlá Ọba tó lòde
òrun |
The King that rules
the great beyond |
|
Bàbá àwa Ọmọ rẹ là ń pè
ó |
Father, we the
children are calling upon you |
|
Láti wá gba ìre tiwa |
For you to accept our
prayer. |
|
OLÓDÙMARÈ tatí were kí o
wá gbáhǜn àwa Ọmọ rẹ |
Olodumare listen to
the joyful voice of your children |
|
Bí o
bá gbó kí o múu şẹ |
When you listen, will
you please accept our request |
|
Ibi kíbi tí abá ńlọ máà
jékí a bó sówó ikú |
Wherever we go, make
our journey safe and prevent our death |
|
Gbogbo ojúmó tóbá ti nmó
ire ni kó máajé fún wa |
All of the beautiful
mornings that we will see, let them be protected for us |
|
Máajé kí Èsù ó báwa jà |
Absolute guidance of
Èsù protection. |
|
Abè ó lórúkọ ÒRÌŞÀ
Àkúnlè bọ |
We appeal you in the
name of all the Orisha we kneel down to revere |
|
Àti lórúkọ ÒRÌŞÀ Àbèrè
bo |
And appeal to you in
the name of all the Orisha we bend down to revere |
|
Àti lórúkọ ÒRÌŞÀ Ádúró
bo |
And appeal to you in
the name of all the Orisha we stand to revere |
|
Kí ààbo rẹ èti ìràńwó rẹ
ó máa báwa gbé ní gbogbo ọjó |
Let your guidance and
your assistance be with us forever and ever |
|
Kí ó şẹ béè! Kí ó şẹ béè!!
Kí ó şẹ béè!!! |
So shall it be! So
shall it be!! So shall it be!!! |
|
Èlà ìború! Èlà bòyè!!
Èlà boşíşe.!!! |
Èlà ìború! Èlà bòyè!!
Èlà boşíşe.!!! |
|
ORIN 2 |
SONG 2 (Repeat
of Opening) |
|
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi oò |
Acceptance of ÒRÌŞÀ
blessings from my voice |
|
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi |
Acceptance of ÒRÌŞÀ
blessings from my mouth |
|
Gbogbo ìre tí mo bá mòmò
sú òò |
All my positive
affirmation and prayers |
|
Ni IRÚNMỌLÈ o gbàà |
Will be accepted by
the IRÚNMỌLÈ |
|
Yío gbàá òò |
Absolutely accepted |
|
. Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi |
Acceptance of ÒRÌŞÀ
blessings from my mouth |
|
ORIN 3 |
SONG 3
(Closing) |
|
Bí mo dúró, bí mo súre |
If I'm standing, I'm
praying |
|
Bi mo
bèrè, bí mo súre |
If
I'm bending, I'm praying |
|
Bi mo
jòkó, bí mo súre |
If
I'm sitting, I'm praying |
|
Ìre tí
mo sù |
All
my prayer |
|
ori ti
gbó |
Has
been accepted |